Mat 7:16-20
Mat 7:16-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn? Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu. Igi rere ko le so eso buburu, bẹ̃ni igi buburu ko si le so eso rere. Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná. Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn.
Mat 7:16-20 Yoruba Bible (YCE)
Nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. Kò sí ẹni tí ó lè ká èso àjàrà lórí igi ẹ̀wọ̀n agogo tabi kí ó rí èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹ̀gún ọ̀gàn. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni: gbogbo igi tí ó bá dára a máa so èso tí ó dára; igi tí kò bá dára a máa so èso burúkú. Igi tí ó bá dára kò lè so èso burúkú; bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lè so èso rere. Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná. Nítorí náà nípa èso wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n.
Mat 7:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.