Mat 7:13-23

Mat 7:13-23 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ gba ẹnu ọ̀nà tí ó fún wọlé. Ọ̀nà ọ̀run àpáàdì gbòòrò, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń gba ibẹ̀. Ṣugbọn ọ̀nà ìyè há, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fún. Díẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n rí i. “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn wolii èké tí wọn máa ń wá sọ́dọ̀ yín. Ní òde, wọ́n dàbí aguntan, ṣugbọn ninu, ìkookò tí ó ya ẹhànnà ni wọ́n. Nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. Kò sí ẹni tí ó lè ká èso àjàrà lórí igi ẹ̀wọ̀n agogo tabi kí ó rí èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹ̀gún ọ̀gàn. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni: gbogbo igi tí ó bá dára a máa so èso tí ó dára; igi tí kò bá dára a máa so èso burúkú. Igi tí ó bá dára kò lè so èso burúkú; bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lè so èso rere. Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná. Nítorí náà nípa èso wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. “Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa’ ni yóo wọ ìjọba ọ̀run, bíkòṣe àwọn tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wí fún mi ní ọjọ́ ìdájọ́ pé, ‘Oluwa, Oluwa, a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní orúkọ rẹ; a lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ; a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ rẹ.’ Ṣugbọn n óo wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi wọnyi!’

Mat 7:13-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín. “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn. “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’ Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’

Mat 7:13-23

Mat 7:13-23 YBCVMat 7:13-23 YBCV