Mat 7:12-20
Mat 7:12-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi li ofin ati awọn woli. Ẹ ba ẹnu-ọ̀na hihá wọle; gbòro li ẹnu-ọ̀na na, ati onibú li oju ọ̀na na ti o lọ si ibi iparun; òpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibẹ̀ wọle. Nitori pe hihá ni ẹnu-ọ̀na na, ati toro li oju-ọ̀na na, ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i. Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu. Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn? Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu. Igi rere ko le so eso buburu, bẹ̃ni igi buburu ko si le so eso rere. Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná. Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn.
Mat 7:12-20 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà, gbogbo bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà ṣe sí wọn. Kókó Òfin ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii nìyí. “Ẹ gba ẹnu ọ̀nà tí ó fún wọlé. Ọ̀nà ọ̀run àpáàdì gbòòrò, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń gba ibẹ̀. Ṣugbọn ọ̀nà ìyè há, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fún. Díẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n rí i. “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn wolii èké tí wọn máa ń wá sọ́dọ̀ yín. Ní òde, wọ́n dàbí aguntan, ṣugbọn ninu, ìkookò tí ó ya ẹhànnà ni wọ́n. Nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. Kò sí ẹni tí ó lè ká èso àjàrà lórí igi ẹ̀wọ̀n agogo tabi kí ó rí èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹ̀gún ọ̀gàn. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni: gbogbo igi tí ó bá dára a máa so èso tí ó dára; igi tí kò bá dára a máa so èso burúkú. Igi tí ó bá dára kò lè so èso burúkú; bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lè so èso rere. Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná. Nítorí náà nípa èso wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n.
Mat 7:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì. “Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín. “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.