Mat 6:9-18
Mat 6:9-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye. Fun wa li onjẹ õjọ wa loni. Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa. Má si fà wa sinu idẹwò, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin. Nitori bi ẹnyin ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin. Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ki yio si fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin. Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ; Ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.
Mat 6:9-18 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run: Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá. Má fà wá sinu ìdánwò, ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’ “Nítorí bí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jì wọ́n, Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo dáríjì yín. Ṣugbọn bí ẹ kò bá dáríjì àwọn eniyan, Baba yín kò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. “Nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ má máa ṣe bí àwọn aláṣehàn tí wọ́n máa ń fajúro, kí àwọn eniyan lè rí i lójú wọn pé wọ́n ń gbààwẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, bọ́jú kí o sì fi nǹkan pa ara, kí ó má baà hàn sí àwọn eniyan pé ò ń gbààwẹ̀, àfi sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san fún ọ.
Mat 6:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín, Kí ìjọba yín dé, Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe ní ayé bí ti ọ̀run. Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí Ẹ dárí gbèsè wa jì wá, Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa, Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò, Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi. Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’ Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò ní í dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbààwẹ̀, ẹ má ṣe fa ojú ro bí àwọn àgàbàgebè ṣe máa ń ṣe nítorí wọn máa ń fa ojú ro láti fihàn àwọn ènìyàn pé àwọn ń gbààwẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín wọn ti gba èrè wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá gbààwẹ̀, bu òróró sí orí rẹ, kí ó sì tún ojú rẹ ṣe dáradára. Kí ó má ṣe hàn sí ènìyàn pé ìwọ ń gbààwẹ̀, bí kò ṣe sì í Baba rẹ, ẹni tí ìwọ kò rí, àti pé, Baba rẹ tí ó rí ohun tí o ṣe ni ìkọ̀kọ̀, yóò san án fún ọ.