Mat 6:9-12
Mat 6:9-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye. Fun wa li onjẹ õjọ wa loni. Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa.
Mat 6:9-12 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run: Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá.
Mat 6:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín, Kí ìjọba yín dé, Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe ní ayé bí ti ọ̀run. Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí Ẹ dárí gbèsè wa jì wá, Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa