Mat 6:6-7
Mat 6:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ̀ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkùn rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ máṣe atunwi asan bi awọn keferi; nwọn ṣebi a o ti itori ọ̀rọ pipọ gbọ́ ti wọn.
Mat 6:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà.
Mat 6:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ìlẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn.


