Mat 6:2-4
Mat 6:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe fun fère niwaju rẹ, bi awọn agabagebe ti nṣe ni sinagogu ati ni ita, ki nwọn ki o le gbà iyìn enia. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. Ṣugbọn nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe jẹ ki ọwọ́ òsi rẹ ki o mọ̀ ohun ti ọwọ́ ọtún rẹ nṣe; Ki itọrẹ ãnu rẹ ki o le wà ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ, on tikararẹ̀ yio san a fun ọ ni gbangba.
Mat 6:2-4 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà, nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe gbé agogo síta gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣehàn tí ń ṣe ninu àwọn ilé ìpàdé ati ní ojú títì ní ìgboro, kí wọn lè gba ìyìn eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má tilẹ̀ jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe; kí ìtọrẹ àánú rẹ jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ yóo sì san ẹ̀san rẹ fún ọ.
Mat 6:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí náà, nígbà ti ẹ́ bá ti ń fún aláìní, ẹ má ṣe fi fèrè kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní Sinagọgu àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń fi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mí mọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ.