Mat 6:19-23
Mat 6:19-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ máṣe tò iṣura jọ fun ara nyin li aiye, nibiti kòkoro ati ipãra ibà a jẹ, ati nibiti awọn olè irunlẹ ti nwọn si ijale: Ṣugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipãra ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale. Nitori nibiti iṣura nyin bá gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu. Oju ni fitila ara: nitorina bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ ni yio kún fun imọlẹ. Ṣugbọn bi oju rẹ ba ṣõkùn, gbogbo ara rẹ ni yio kun fun òkunkun. Njẹ bi imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ba jẹ́ òkunkun, òkunkun na yio ti pọ̀ to!
Mat 6:19-23 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ má ṣe kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ayé, níbi tí kòkòrò lè bà á jẹ́, tí ó sì lè dógùn-ún. Àwọn olè tún lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ. Ṣugbọn ẹ kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò kò lè bà á jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè dógùn-ún, àwọn olè kò sì lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ níbẹ̀. Nítorí níbi tí ìṣúra rẹ bá wà, níbẹ̀ náà ni ọkàn rẹ yóo wà. “Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran tààrà, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu rẹ bá wá di òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn náà yóo ti pọ̀ tó!
Mat 6:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú. “Ojú ni fìtílà ara. Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó!