Mat 6:1-8

Mat 6:1-8 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn yín, ẹ má máa hùwà ṣe-á-rí-mi, kí àwọn eniyan baà lè rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe. Bí ẹ bá ń hùwà ṣe-á-rí-mi, ẹ kò ní èrè lọ́dọ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. “Nítorí náà, nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe gbé agogo síta gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣehàn tí ń ṣe ninu àwọn ilé ìpàdé ati ní ojú títì ní ìgboro, kí wọn lè gba ìyìn eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má tilẹ̀ jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe; kí ìtọrẹ àánú rẹ jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ yóo sì san ẹ̀san rẹ fún ọ. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má ṣe bí àwọn aláṣehàn. Nítorí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa dúró gbadura ninu ilé ìpàdé ati ní ẹ̀bá títì, kí àwọn eniyan lè rí wọn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà. Ẹ má ṣe fara wé wọn, nítorí Baba yín ti mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

Mat 6:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò ni èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run. “Nítorí náà, nígbà ti ẹ́ bá ti ń fún aláìní, ẹ má ṣe fi fèrè kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní Sinagọgu àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń fi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mí mọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ. “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní Sinagọgu àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ìlẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.