Mat 5:43-47
Mat 5:43-47 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ, ki iwọ si korira ọtá rẹ. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin; Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ ràn sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ. Nitori bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? Bi ẹnyin ba si nkí kìki awọn arakunrin nyin, kili ẹ ṣe jù awọn ẹlomiran lọ? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe?
Mat 5:43-47 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ pé, ‘Fẹ́ràn aládùúgbò rẹ, kí o kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí ó ṣe inúnibíni yín. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ti di ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. Nítorí a máa mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere; a sì máa rọ òjò sórí àwọn olódodo ati sórí àwọn alaiṣododo. Nítorí bí ẹ bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín, èrè wo ni ó wà níbẹ̀? Mo ṣebí àwọn agbowó-odè náà a máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tí ẹ bá ń kí àwọn arakunrin yín nìkan, kí ni ẹ ṣe ju àwọn ẹlòmíràn lọ? Mo ṣebí àwọn abọ̀rìṣà náà ń ṣe bẹ́ẹ̀!
Mat 5:43-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín. Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo. Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́? Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn lọ? Àwọn kèfèrí kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí?