Mat 5:27-32
Mat 5:27-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ ṣe panṣaga. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wò obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹ si i, o ti bá a ṣe panṣaga tan li ọkàn rẹ̀. Bi oju ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. Bi ọwọ́ ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. A ti wi pẹlu pe, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, jẹ ki o fi iwe ìkọsilẹ le e lọwọ. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe nitori àgbere, o mu u ṣe panṣaga; ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.
Mat 5:27-32 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obinrin pẹlu èrò láti bá a lòpọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ kí ó ṣègbé jù pé kí á sọ gbogbo ara rẹ sí ọ̀run àpáàdì lọ. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ ó ṣègbé jù kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì lọ. “Wọ́n sọ pé, ‘Ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ níláti fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìjẹ́ pé aya yìí ṣe ìṣekúṣe, ó mú un ṣe àgbèrè. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ obinrin tí a kọ̀ sílẹ̀, òun náà ṣe àgbèrè.
Mat 5:27-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. “A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.