Mat 5:2-6
Mat 5:2-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si yà ẹnu rẹ̀, o si kọ́ wọn, wipe: Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmí: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. Alabukún-fun li awọn ẹniti nkãnu: nitoriti a ó tù wọn ninu. Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye. Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo.
Mat 5:2-6 Yoruba Bible (YCE)
Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé: “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó.
Mat 5:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn. Ó wí pé: “Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú. Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí wọn yóò jogún ayé. Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.