Mat 5:19-20
Mat 5:19-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnikẹni ti o ba rú ọkan kikini ninu ofin wọnyi, ti o ba si nkọ́ awọn enia bẹ̃, on na li a o pè ni kikini ni ijọba ọrun: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nṣe wọn ti o ba si nkọ́ wọn, on na li a o pè ni ẹni-nla ni ijọba ọrun. Nitori mo wi fun nyin, bikoṣepe ododo nyin ba kọja ododo awọn akọwe ati ti awọn Farisi, ẹnyin kì yio le de ilẹ-ọba ọrun bi o ti wù ki o ri.
Mat 5:19-20 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá rú èyí tí ó kéré jùlọ ninu àwọn òfin wọnyi, tí ó sì tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di ẹni ìkẹyìn patapata ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń pa àwọn àṣẹ wọnyi mọ́, tí ó tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di aṣiwaju ní ìjọba ọ̀run. Nítorí mo wí fun yín pé bí òdodo yín kò bá tayọ ti àwọn amòfin ati ti àwọn Farisi, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run.
Mat 5:19-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.