Mat 4:9-10
Mat 4:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ó fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o si foribalẹ fun mi. Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Pada kuro lẹhin mi, Satani: nitori a kọwe rẹ̀ pe, Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mã sìn.
Pín
Kà Mat 4Mat 4:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Ó bá sọ fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọnyi ni n óo fún ọ bí o bá wolẹ̀ tí o júbà mi.” Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ”
Pín
Kà Mat 4Mat 4:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.” Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”
Pín
Kà Mat 4