Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Mat 4:8-10

Mat 4:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)

Èṣu gbé e lọ si ori òke giga-giga ẹ̀wẹ, o si fi gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn hàn a; O si wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ó fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o si foribalẹ fun mi. Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Pada kuro lẹhin mi, Satani: nitori a kọwe rẹ̀ pe, Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mã sìn.

Pín
Kà Mat 4

Mat 4:8-10 Yoruba Bible (YCE)

Èṣù tún mú un lọ sórí òkè gíga kan; ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án. Ó bá sọ fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọnyi ni n óo fún ọ bí o bá wolẹ̀ tí o júbà mi.” Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ”

Pín
Kà Mat 4

Mat 4:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.” Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”

Pín
Kà Mat 4
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò