Mat 4:3-8
Mat 4:3-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati oludanwò de ọdọ rẹ̀, o ni, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ ki okuta wọnyi di akara. Ṣugbọn o dahùn wipe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Enia kì yio wà lãyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá. Nigbana ni Èṣu gbé e lọ soke si ilu mimọ́ nì, o gbé e le ṣonṣo tẹmpili, O si wi fun u pe, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, li ọwọ́ wọn ni nwọn o si gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta. Jesu si wi fun u pe, A tún kọ ọ pe, Iwọ ko gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò. Èṣu gbé e lọ si ori òke giga-giga ẹ̀wẹ, o si fi gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn hàn a
Mat 4:3-8 Yoruba Bible (YCE)
Ni adánniwò bá yọ sí i, ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, sọ fún àwọn òkúta wọnyi kí wọ́n di àkàrà.” Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun bá sọ.’ ” Lẹ́yìn náà, Èṣù mú un lọ sí Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ nì, ó gbé e lé góńgó orí Tẹmpili. Ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ, kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà ọ́, kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ” Jesu sọ fún un pé, “Ó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ” Èṣù tún mú un lọ sórí òkè gíga kan; ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án.
Mat 4:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.” Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ” Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili. Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sá à ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí tìrẹ wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ” Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ” Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án.