Mat 4:21-22
Mat 4:21-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o si ti ti ibẹ lọ siwaju, o ri awọn arakunrin meji, Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, nwọn ndí àwọn wọn; o si pè wọn. Lojukanna nwọn si fi ọkọ̀ ati baba wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.
Mat 4:21-22 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó ti kúrò níbẹ̀ tí ó lọ siwaju díẹ̀ sí i, ó rí àwọn arakunrin meji mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀. Wọ́n wà ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó bá pè wọ́n. Lẹsẹkẹsẹ, wọ́n fi ọkọ̀ ati baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀lé e.
Mat 4:21-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.