Mat 4:18-25
Mat 4:18-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu nrin leti okun Galili, o ri awọn arakunrin meji, Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitori nwọn jẹ apẹja. O si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia. Nwọn si fi àwọn silẹ lojukanna, nwọn sì tọ̀ ọ lẹhin. Bi o si ti ti ibẹ lọ siwaju, o ri awọn arakunrin meji, Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, nwọn ndí àwọn wọn; o si pè wọn. Lojukanna nwọn si fi ọkọ̀ ati baba wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagogu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia. Okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo Siria ká; nwọn si gbé awọn alaisàn ti o ni onirũru àrun ati irora wá sọdọ rẹ̀, ati awọn ti o li ẹmi èṣu, ati awọn ti o nsinwin, ati awọn ti o li ẹ̀gba; o si wò wọn sàn. Ọpọlọpọ enia si tọ̀ ọ lẹhin lati Galili, ati Dekapoli, ati Jerusalemu, ati lati Judea wá, ati lati oke odò Jordani.
Mat 4:18-25 Yoruba Bible (YCE)
Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, kì í ṣe ẹja ni ẹ óo máa pamọ́, eniyan ni ẹ óo máa fà wá.” Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Bí ó ti kúrò níbẹ̀ tí ó lọ siwaju díẹ̀ sí i, ó rí àwọn arakunrin meji mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀. Wọ́n wà ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó bá pè wọ́n. Lẹsẹkẹsẹ, wọ́n fi ọkọ̀ ati baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀lé e. Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Siria. Àwọn eniyan ń gbé gbogbo àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú, ati àwọn tí wárápá mú ati àwọn arọ; ó sì ń wò wọ́n sàn. Ọpọlọpọ eniyan ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili ati Ìlú Mẹ́wàá ati Jerusalẹmu ati Judia, ati láti òdìkejì Jọdani.
Mat 4:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.