Mat 4:16-18
Mat 4:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn enia ti o joko li òkunkun ri imọlẹ nla; ati awọn ti o joko ni ibi iku ati labẹ ojiji rẹ̀ ni imọlẹ là fun. Lati igbana ni Jesu bẹ̀rẹ si iwasu wipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ. Jesu nrin leti okun Galili, o ri awọn arakunrin meji, Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitori nwọn jẹ apẹja.
Mat 4:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn eniyan tí ó jókòó ní òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ mọ́ sórí àwọn tí ó jókòó ní ilẹ̀ tí òjìji ikú wà.” Láti àkókò yìí ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu pé, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba ọ̀run súnmọ́ ìtòsí.” Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.
Mat 4:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá, àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.” Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n.