Mat 4:14-17
Mat 4:14-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki eyi ti a wi lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, Ilẹ Sebuloni ati ilẹ Neftalimu li ọ̀na okun, li oke Jordani, Galili awọn keferi; Awọn enia ti o joko li òkunkun ri imọlẹ nla; ati awọn ti o joko ni ibi iku ati labẹ ojiji rẹ̀ ni imọlẹ là fun. Lati igbana ni Jesu bẹ̀rẹ si iwasu wipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ.
Mat 4:14-17 Yoruba Bible (YCE)
Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé: “Ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali, ní ọ̀nà òkun, ní òdìkejì Jọdani, Galili àwọn àjèjì. Àwọn eniyan tí ó jókòó ní òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ mọ́ sórí àwọn tí ó jókòó ní ilẹ̀ tí òjìji ikú wà.” Láti àkókò yìí ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu pé, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba ọ̀run súnmọ́ ìtòsí.”
Mat 4:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé: “ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftali ọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani, Galili ti àwọn kèfèrí. Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá, àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.” Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”