Mat 3:7-10
Mat 3:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ awọn Farisi ati Sadusi wá si baptismu rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀? Nitorina, ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada: Ki ẹ má si ṣe rò ninu ara nyin, wipe, Awa ní Abrahamu ni baba; ki emi wi fun nyin, Ọlọrun le yọ ọmọ jade lati inu okuta wọnyi wá fun Abrahamu. Ati nisisiyi pẹlu, a ti fi ãke le gbòngbo igi na; nitorina gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a o ke e lùlẹ, a o si wọ́ ọ jù sinu iná.
Mat 3:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ninu àwọn Farisi ati Sadusi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí ó ṣe ìrìbọmi fún wọn, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀? Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má ṣe rò lọ́kàn yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mo ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi. A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí, nítorí náà, igikígi tí kò bá so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo fi dáná.
Mat 3:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisi àti Sadusi tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà. Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Abrahamu. Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò ge lulẹ̀ ti a ó sì wọ jù sínú iná.