Skip to content
Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Mat 3:7YBCV(Bibeli Mimọ)

Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ awọn Farisi ati Sadusi wá si baptismu rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀?

Mat 3:7BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisi àti Sadusi tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?

Mat 3:7YCE(Yoruba Bible)

Ṣugbọn nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ninu àwọn Farisi ati Sadusi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí ó ṣe ìrìbọmi fún wọn, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀?