Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Mat 3:11-12

Mat 3:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, bàta ẹniti emi ko to gbé; on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin. Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, yio si gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, yio si kó alikama rẹ̀ sinu abà, ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun.

Pín
Kà Mat 3

Mat 3:11-12 Yoruba Bible (YCE)

Ìrìbọmi ni èmi fi ń wẹ̀ yín mọ́ nítorí ìrònúpìwàdà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi jù mí lọ; èmi kò tó ẹni tí ó lè kó bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni òun yóo fi wẹ̀ yín mọ́. Àtẹ ìfẹ́kà rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tótó. Yóo kó ọkà rẹ̀ jọ sinu abà, ṣugbọn sísun ni yóo sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.”

Pín
Kà Mat 3

Mat 3:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Èmi fi omi bamitiisi yín fún ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó pọ̀jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín. Ẹni ti àmúga ìpakà rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó alikama rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”

Pín
Kà Mat 3
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò