Mat 3:1-4
Mat 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NI ijọ wọnni ni Johanu Baptisti wá, o nwasu ni ijù Judea, O si nwipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀. Nitori eyi li ẹniti woli Isaiah sọ ọ̀rọ rẹ̀, wipe, Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju-ọ̀na rẹ̀ tọ́. Aṣọ Johanu na si jẹ ti irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ si ẹ̀gbẹ rẹ̀; onjẹ rẹ̀ li ẽṣú ati oyin ìgan.
Mat 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, Johanu Onítẹ̀bọmi dé, ó ń waasu ní aṣálẹ̀ Judia. Ó ní, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba Ọlọrun fẹ́rẹ̀ dé.” Nítorí òun ni wolii Aisaya sọ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹnìkan tí ó ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà tí OLUWA yóo gbà, ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ” Johanu yìí wọ aṣọ tí a fi irun ràkúnmí hun, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí. Oúnjẹ rẹ̀ ni ẹṣú ati oyin ìgàn.
Mat 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Johanu onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Judea. Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.