Mat 3:1-12
Mat 3:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
NI ijọ wọnni ni Johanu Baptisti wá, o nwasu ni ijù Judea, O si nwipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀. Nitori eyi li ẹniti woli Isaiah sọ ọ̀rọ rẹ̀, wipe, Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju-ọ̀na rẹ̀ tọ́. Aṣọ Johanu na si jẹ ti irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ si ẹ̀gbẹ rẹ̀; onjẹ rẹ̀ li ẽṣú ati oyin ìgan. Nigbana li awọn ara Jerusalemu, ati gbogbo Judea, ati gbogbo ẹkùn apa Jordani yiká jade tọ̀ ọ wá, A si mbaptisi wọn lọdọ rẹ̀ ni odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn. Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ awọn Farisi ati Sadusi wá si baptismu rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀? Nitorina, ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada: Ki ẹ má si ṣe rò ninu ara nyin, wipe, Awa ní Abrahamu ni baba; ki emi wi fun nyin, Ọlọrun le yọ ọmọ jade lati inu okuta wọnyi wá fun Abrahamu. Ati nisisiyi pẹlu, a ti fi ãke le gbòngbo igi na; nitorina gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a o ke e lùlẹ, a o si wọ́ ọ jù sinu iná. Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, bàta ẹniti emi ko to gbé; on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin. Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, yio si gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, yio si kó alikama rẹ̀ sinu abà, ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun.
Mat 3:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, Johanu Onítẹ̀bọmi dé, ó ń waasu ní aṣálẹ̀ Judia. Ó ní, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba Ọlọrun fẹ́rẹ̀ dé.” Nítorí òun ni wolii Aisaya sọ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹnìkan tí ó ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà tí OLUWA yóo gbà, ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ” Johanu yìí wọ aṣọ tí a fi irun ràkúnmí hun, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí. Oúnjẹ rẹ̀ ni ẹṣú ati oyin ìgàn. Nígbà náà ni àwọn eniyan láti Jerusalẹmu ati gbogbo ilẹ̀ Judia ati ní gbogbo ìgbèríko odò Jọdani ń jáde tọ̀ ọ́ lọ. Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani. Ṣugbọn nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ninu àwọn Farisi ati Sadusi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí ó ṣe ìrìbọmi fún wọn, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀? Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má ṣe rò lọ́kàn yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mo ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi. A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí, nítorí náà, igikígi tí kò bá so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo fi dáná. Ìrìbọmi ni èmi fi ń wẹ̀ yín mọ́ nítorí ìrònúpìwàdà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi jù mí lọ; èmi kò tó ẹni tí ó lè kó bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni òun yóo fi wẹ̀ yín mọ́. Àtẹ ìfẹ́kà rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tótó. Yóo kó ọkà rẹ̀ jọ sinu abà, ṣugbọn sísun ni yóo sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.”
Mat 3:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Johanu onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Judea. Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerusalẹmu àti gbogbo Judea àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jordani. Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a sì ń bamitiisi wọn ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní odò Jordani. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisi àti Sadusi tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà. Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Abrahamu. Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò ge lulẹ̀ ti a ó sì wọ jù sínú iná. “Èmi fi omi bamitiisi yín fún ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó pọ̀jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín. Ẹni ti àmúga ìpakà rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó alikama rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”