Mat 28:1-10

Mat 28:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Maria Magdalene àti Maria kejì lọ sí ibojì. Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí angẹli Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí. Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wárìrì wọn sì dàbí òkú. Nígbà náà ni angẹli náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí. Nísinsin yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Galili síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò gbé rí i,’ wò ó, o ti sọ fún yin.” Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìròyìn tí angẹli náà fi fún wọn. Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jesu pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà” Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Galili níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ”