Mat 27:50-52
Mat 27:50-52 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde
Pín
Kà Mat 27Mat 27:50-52 Yoruba Bible (YCE)
Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán. Òkúta ẹnu ibojì ṣí, a sì jí ọ̀pọ̀ òkú àwọn olódodo dìde.
Pín
Kà Mat 27Mat 27:50-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú. Lójúkan náà aṣọ ìkélé tẹmpili fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán. Àwọn isà òkú sì ṣí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tí ó ti sùn sì tún jíǹde.
Pín
Kà Mat 27