Mat 27:41-43
Mat 27:41-43 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu awọn akọwe, ati awọn àgbãgba nfi ṣe ẹlẹya, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́. O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi.
Mat 27:41-43 Yoruba Bible (YCE)
Bákan náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà, àwọn náà ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń sọ pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó rí gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Ṣé ọba Israẹli ni! Kí ó sọ̀kalẹ̀ nisinsinyii láti orí agbelebu, a óo gbà á gbọ́. Ṣé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ni! Kí Ọlọrun gbà á sílẹ̀ nisinsinyii bí ó bá fẹ́ ẹ! Ṣebí ó sọ pé ọmọ Ọlọrun ni òun.”
Mat 27:41-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?”