Mat 27:32-34
Mat 27:32-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi nwọn si ti jade, nwọn ri ọkunrin kan ara Kirene, ti njẹ Simoni: on ni nwọn fi agbara mu lati rù agbelebu rẹ̀. Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Golgota, eyini ni, Ibi agbari, Nwọn fi ọti kikan ti a dàpọ mọ orõrò fun u lati mu: nigbati o si tọ́ ọ wò, o kọ̀ lati mu u.
Mat 27:32-34 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọn ń jáde lọ, wọ́n rí ọkunrin kan ará Kirene tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni. Wọ́n bá fi ipá mú un láti ru agbelebu Jesu. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”), wọ́n fún un ní ọtí kíkorò mu. Nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀, kò mu ún.
Mat 27:32-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu. Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.) Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún.