Mat 27:27-44
Mat 27:27-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li awọn ọmọ-ogun Bãlẹ mu Jesu lọ sinu gbọ̀ngan idajọ, nwọn si kó gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun tì i. Nwọn si bọ́ aṣọ rẹ̀, nwọn si wọ̀ ọ li aṣọ ododó. Nwọn si hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori, nwọn si fi ọpá iyè le e li ọwọ́ ọtún: nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si fi i ṣẹsin, wipe, Kabiyesi, ọba awọn Ju. Nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si gbà ọpá iyè na, nwọn si fi lù u li ori. Nigbati nwọn fi i ṣẹsin tan, nwọn bọ aṣọ na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si fa a lọ lati kàn a mọ agbelebu. Bi nwọn si ti jade, nwọn ri ọkunrin kan ara Kirene, ti njẹ Simoni: on ni nwọn fi agbara mu lati rù agbelebu rẹ̀. Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Golgota, eyini ni, Ibi agbari, Nwọn fi ọti kikan ti a dàpọ mọ orõrò fun u lati mu: nigbati o si tọ́ ọ wò, o kọ̀ lati mu u. Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu, nwọn pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gègé le e: ki eyi ti wolĩ wi ba le ṣẹ, pe, Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn aṣọ ileke mi ni nwọn ṣẹ gègé le. Nwọn si joko, nwọn nṣọ ọ nibẹ̀. Nwọn si fi ọ̀ran ifisùn rẹ̀ ti a kọ si igberi rẹ̀, EYI NI JESU ỌBA AWỌN JU. Nigbana li a kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi. Awọn ti nkọja lọ si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, Wipe, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, gbà ara rẹ là. Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu awọn akọwe, ati awọn àgbãgba nfi ṣe ẹlẹya, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́. O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi. Awọn olè ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nfi eyi na gún u loju bakanna.
Mat 27:27-44 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí. Wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n wá fi aṣọ àlàárì bò ó lára. Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń wí pé, “Kabiyesi, ọba àwọn Juu.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tutọ́ sí i lára. Wọ́n mú ọ̀pá, wọ́n ń kán an mọ́ ọn lórí. Nígbà tí wọn ti fi ṣe ẹlẹ́yà tẹ́rùn, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n fi tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n bá mú un lọ láti kàn án mọ́ agbelebu. Nígbà tí wọn ń jáde lọ, wọ́n rí ọkunrin kan ará Kirene tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni. Wọ́n bá fi ipá mú un láti ru agbelebu Jesu. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”), wọ́n fún un ní ọtí kíkorò mu. Nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀, kò mu ún. Nígbà tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu tán, wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá jókòó níbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ. Wọ́n fi àkọlé kan kọ́ sí òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án sibẹ pé, “Eléyìí ni Jesu ọba àwọn Juu.” Wọ́n tún kan àwọn ọlọ́ṣà meji mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i. Wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là. Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́, sọ̀kalẹ̀ kúrò lórí agbelebu.” Bákan náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà, àwọn náà ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń sọ pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó rí gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Ṣé ọba Israẹli ni! Kí ó sọ̀kalẹ̀ nisinsinyii láti orí agbelebu, a óo gbà á gbọ́. Ṣé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ni! Kí Ọlọrun gbà á sílẹ̀ nisinsinyii bí ó bá fẹ́ ẹ! Ṣebí ó sọ pé ọmọ Ọlọrun ni òun.” Bákan náà ni àwọn ọlọ́ṣà tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ fi ń ṣe ẹlẹ́yà.
Mat 27:27-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gómìnà mú Jesu lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í Wọ́n tú Jesu sì ìhòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ òdòdó, Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí. Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu. Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.) Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀. Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé: “èyí ni jesu, ọba àwọn júù” síbẹ̀. Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé: “Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!” Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?” Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.