Mat 26:3-5
Mat 26:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li awọn olori alufa, awọn akọwe, ati awọn àgba awọn enia pejọ li ãfin olori alufa, ẹniti a npè ni Kaíafa, Nwọn si jọ gbìmọ lati fi ẹ̀tan mu Jesu, ki nwọn si pa a. Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia.
Mat 26:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú péjọ sí àgbàlá Olórí Alufaa tí ó ń jẹ́ Kayafa. Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á. Ṣugbọn wọ́n ń sọ pé, “Kí á má ṣe é ní àkókò àjọ̀dún, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìlú yóo dàrú.”
Mat 26:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àsìkò tí Jesu ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfáà náà tí à ń pè ní Kaiafa. Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á. Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”