Mat 26:17-20
Mat 26:17-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigba ọjọ ikini ajọ aiwukara, awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse silẹ dè ọ lati jẹ irekọja? O si wipe, Ẹ wọ̀ ilu lọ si ọdọ ọkunrin kan bayi, ẹ si wi fun u pe, Olukọni wipe, Akokò mi sunmọ etile; emi o ṣe ajọ irekọja ni ile rẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi. Awọn ọmọ-ẹhin na si ṣe gẹgẹ bi Jesu ti fi aṣẹ fun wọn; nwọn si pèse irekọja silẹ. Nigbati alẹ si lẹ, o joko pẹlu awọn mejila.
Mat 26:17-20 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?” Ó bá dáhùn pé, “Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ ọkunrin kan báyìí nígboro kí ẹ sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ni ní: Àkókò mi súnmọ́ tòsí; ní ilé rẹ ni èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yóo ti jẹ àsè Ìrékọjá.’ ” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn mejila.
Mat 26:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jesu wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?” Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ” Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀. Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jesu ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá