Mat 25:26-30
Mat 25:26-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa rẹ̀ si dahùn o wi fun u pe, Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi nkore nibiti emi kò funrugbin si, emi si nṣà nibiti emi kò fẹ́ka si: Nitorina iwọ iba fi owo mi si ọwọ́ awọn ti npowodà, nigbati emi ba de, emi iba si gbà nkan mi pẹlu elé. Nitorina ẹ gbà talenti na li ọwọ́ rẹ̀, ẹ si fifun ẹniti o ni talenti mẹwa. Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ́ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni. Ẹ si gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.
Mat 25:26-30 Yoruba Bible (YCE)
“Olúwa rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ olubi ati onímẹ̀ẹ́lẹ́ ẹrú yìí. O mọ̀ pé èmi a máa kórè níbi tí n kò fúnrúgbìn sí, ati pé èmi a máa fojú wá nǹkan níbi tí n kò fi pamọ́ sí. Nígbà tí o mọ̀ bẹ́ẹ̀, kí ni kò jẹ́ kí o fi owó mi fún àwọn agbowó-pamọ́ pé nígbà tí mo bá dé, kí n lè gba owó mi pada pẹlu èlé? Nítorí náà, ẹ gba àpò kan náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní àpò mẹ́wàá. Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a óo túbọ̀ fún, kí ó lè ní sí i. Lọ́wọ́ ẹni tí kò ní ni a óo sì ti gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní. Kí ẹ mú ẹrú tí kò wúlò yìí kí ẹ tì í sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’
Mat 25:26-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kójọ níbi tí èmi kò fọ́nká ká sí. Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè. “ ‘Ó sì pàṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní. Nítorí ìdí èyí, gbé aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ ni ẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’