Mat 25:1-5
Mat 25:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA li a o fi ijọba ọrun wé awọn wundia mẹwa, ti o mu fitila wọn, ti nwọn si jade lọ ipade ọkọ iyawo. Marun ninu wọn ṣe ọlọgbọn, marun si ṣe alaigbọn. Awọn ti o ṣe alaigbọ́n mu fitila wọn, nwọn kò si mu oróro lọwọ: Ṣugbọn awọn ọlọgbọn mu oróro ninu kolobo pẹlu fitila wọn. Nigbati ọkọ iyawo pẹ, gbogbo wọn tõgbé, nwọn si sùn.
Mat 25:1-5 Yoruba Bible (YCE)
“Ní àkókò náà, ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run yóo dàbí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn wundia mẹ́wàá, tí wọn gbé àtùpà wọn láti jáde lọ pàdé ọkọ iyawo. Marun-un ninu wọn jẹ́ òmùgọ̀, marun-un sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Àwọn òmùgọ̀ gbé àtùpà, ṣugbọn wọn kò gbé epo lọ́wọ́. Àwọn ọlọ́gbọ́n rọ epo sinu ìgò, wọ́n gbé e lọ́wọ́ pẹlu àtùpà wọn. Nígbà tí ọkọ iyawo pẹ́ kí ó tó dé, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé, wọ́n bá sùn lọ.
Mat 25:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó. Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́. Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó lọ́wọ́ pẹ̀lú fìtílà wọn. Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn.