Mat 25:1-3
Mat 25:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA li a o fi ijọba ọrun wé awọn wundia mẹwa, ti o mu fitila wọn, ti nwọn si jade lọ ipade ọkọ iyawo. Marun ninu wọn ṣe ọlọgbọn, marun si ṣe alaigbọn. Awọn ti o ṣe alaigbọ́n mu fitila wọn, nwọn kò si mu oróro lọwọ
Pín
Kà Mat 25Mat 25:1-3 Yoruba Bible (YCE)
“Ní àkókò náà, ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run yóo dàbí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn wundia mẹ́wàá, tí wọn gbé àtùpà wọn láti jáde lọ pàdé ọkọ iyawo. Marun-un ninu wọn jẹ́ òmùgọ̀, marun-un sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Àwọn òmùgọ̀ gbé àtùpà, ṣugbọn wọn kò gbé epo lọ́wọ́.
Pín
Kà Mat 25Mat 25:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó. Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́.
Pín
Kà Mat 25