Mat 24:6-8
Mat 24:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin o si gburo ogun ati idagìri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi ko le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: ìyan, ati ajakalẹ-arùn, ati iṣẹlẹ̀ yio si wà ni ibi pipọ. Gbogbo nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju.
Mat 24:6-8 Yoruba Bible (YCE)
Àkókò ń bọ̀ tí ẹ óo gbúròó ogun ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun. Ẹ má bẹ̀rù. Èyí níláti rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kò ì tíì tó àkókò tí òpin ayé yóo dé. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo dìde sí orílẹ̀-èdè; ìjọba yóo dìde sí ìjọba. Ìyàn yóo mú. Ilẹ̀ yóo máa mì ní ọpọlọpọ ìlú. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora bíi ti ìrọbí ni gbogbo èyí.
Mat 24:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀.