Mat 24:45-51
Mat 24:45-51 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tani iṣe olõtọ ati ọlọgbọn ọmọ-ọdọ, ẹniti oluwa rẹ̀ fi ṣe olori ile rẹ̀, lati fi onjẹ wọn fun wọn li akokò? Alabukún-fun li ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ẹniti yio bá a ki o mã ṣe bẹ̃. Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, On o fi ṣe olori gbogbo ohun ti o ni. Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ buburu na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi fà àbọ rẹ̀ sẹhin; Ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọ̀muti; Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti, ati ni wakati ti kò daba. Yio si jẹ ẹ ni ìya gidigidi, yio yàn ipa rẹ̀ pẹlu awọn agabagebe, nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.
Mat 24:45-51 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ẹrú kan bá jẹ́ olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n, ọ̀gá rẹ̀ á fi ilé rẹ̀ lé e lọ́wọ́, pé kí ó máa fún àwọn eniyan ní oúnjẹ lásìkò. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹrú náà tí ọ̀gá rẹ̀ bá bá a lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo fi í ṣe olùtọ́jú ohun gbogbo tí ó ní. Ṣugbọn bí ẹrú bá jẹ́ olubi, tí ó bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi kò ní tètè dé!’ Tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu pẹlu àwọn ọ̀mùtí, ọ̀gá ẹrú náà yóo dé ní ọjọ́ tí kò rò, ati ní wakati tí kò lérò. Ọ̀gá rẹ̀ yóo wá nà án, yóo fi í sí ààrin àwọn alaiṣootọ. Níbẹ̀ ni yóo máa gbé sunkún tí yóo sì máa payínkeke.
Mat 24:45-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ǹjẹ́ olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́? Alábùkún fún ni ọmọ ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní. Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú náà bá wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘olúwa mi kì yóò tètè dé.’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara. Nígbà náà ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò retí. Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ibùgbé àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.