Mat 24:4-14
Mat 24:4-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ. Nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn ó si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ. Ẹnyin o si gburo ogun ati idagìri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi ko le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: ìyan, ati ajakalẹ-arùn, ati iṣẹlẹ̀ yio si wà ni ibi pipọ. Gbogbo nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju. Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni ìya, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ède nitori orukọ mi. Nigbana li ọ̀pọlọpọ yio kọsẹ̀, nwọn o si ma ṣòfofo ara wọn, nwọn o si mã korira ara wọn. Wolĩ eke pipọ ni yio si dide, nwọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ. Ati nitori ẹ̀ṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù. Ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà. A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de.
Mat 24:4-14 Yoruba Bible (YCE)
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ ni yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo máa sọ pé, ‘Èmi gan-an ni Mesaya náà,’ wọn yóo sì tan ọpọlọpọ jẹ. Àkókò ń bọ̀ tí ẹ óo gbúròó ogun ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun. Ẹ má bẹ̀rù. Èyí níláti rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kò ì tíì tó àkókò tí òpin ayé yóo dé. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo dìde sí orílẹ̀-èdè; ìjọba yóo dìde sí ìjọba. Ìyàn yóo mú. Ilẹ̀ yóo máa mì ní ọpọlọpọ ìlú. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora bíi ti ìrọbí ni gbogbo èyí. “Ní àkókò náà, wọn yóo fà yín lé àwọn eniyan lọ́wọ́ pé kí wọ́n jẹ yín níyà, kí wọ́n sì pa yín. Gbogbo ará ayé ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ọpọlọpọ yóo kùnà ninu igbagbọ; wọn yóo tú àwọn mìíràn fó; wọn yóo sì kórìíra àwọn mìíràn. Ọpọlọpọ àwọn wolii èké ni yóo dìde, wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ. Nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ yóo gbilẹ̀, ìfẹ́ ọpọlọpọ yóo rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forí tì í títí dé òpin, òun ni a óo gbà là. A óo waasu ìyìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé.
Mat 24:4-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kristi náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀. “Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi. Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà. A ó sì wàásù ìhìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.