Mat 24:32-51
Mat 24:32-51 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; nigbati ẹká rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile: Gẹgẹ bẹ̃ li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ. Ọrun on aiye yio rekọjá, ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja. Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ̀ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo. Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio si ri. Nitori bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kikún omi, ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ́ sinu ọkọ̀, Nwọn kò si mọ̀ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. Nigbana li ẹni meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi èkejì silẹ. Awọn obinrin meji yio jùmọ ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin kò mọ̀ wakati ti Oluwa nyin yio de. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati na ti olè yio wá, iba ma ṣọna, on kì ba ti jẹ́ ki a runlẹ ile rẹ̀. Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de. Tani iṣe olõtọ ati ọlọgbọn ọmọ-ọdọ, ẹniti oluwa rẹ̀ fi ṣe olori ile rẹ̀, lati fi onjẹ wọn fun wọn li akokò? Alabukún-fun li ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ẹniti yio bá a ki o mã ṣe bẹ̃. Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, On o fi ṣe olori gbogbo ohun ti o ni. Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ buburu na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi fà àbọ rẹ̀ sẹhin; Ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọ̀muti; Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti, ati ni wakati ti kò daba. Yio si jẹ ẹ ni ìya gidigidi, yio yàn ipa rẹ̀ pẹlu awọn agabagebe, nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.
Mat 24:32-51 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọnyi, kí ẹ̀yin náà mọ̀ pé àkókò súnmọ́ tòsí, ó ti dé ẹnu ọ̀nà. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán títí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ. “Kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ náà ati wakati náà. Àwọn angẹli ọ̀run kò mọ̀ ọ́n; ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan ni ó mọ̀ ọ́n. Nítorí bí ó ti rí ní ìgbà Noa, bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Nítorí ní àkókò náà, kí ìkún-omi tó dé, ńṣe ni wọ́n ń jẹ, tí wọn ń mu, wọ́n ń gbé iyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí ó fi di ọjọ́ tí Noa wọ inú ọkọ̀. Wọn kò fura títí ìkún-omi fi dé, tí ó gba gbogbo wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Àwọn meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. Àwọn obinrin meji yóo máa lọ ọkà ninu ilé ìlọkà. A óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Oluwa yín ń bọ̀. Ẹ mọ èyí pé bí baálé bá mọ àsìkò tí olè yóo dé, ìbá máa ṣọ́nà, kì bá tí jẹ́ kí olè kó ilé rẹ̀. Nítorí náà, kí ẹ̀yin náà wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wakati tí ẹ kò rò tẹ́lẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo dé. “Bí ẹrú kan bá jẹ́ olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n, ọ̀gá rẹ̀ á fi ilé rẹ̀ lé e lọ́wọ́, pé kí ó máa fún àwọn eniyan ní oúnjẹ lásìkò. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹrú náà tí ọ̀gá rẹ̀ bá bá a lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo fi í ṣe olùtọ́jú ohun gbogbo tí ó ní. Ṣugbọn bí ẹrú bá jẹ́ olubi, tí ó bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi kò ní tètè dé!’ Tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu pẹlu àwọn ọ̀mùtí, ọ̀gá ẹrú náà yóo dé ní ọjọ́ tí kò rò, ati ní wakati tí kò lérò. Ọ̀gá rẹ̀ yóo wá nà án, yóo fi í sí ààrin àwọn alaiṣootọ. Níbẹ̀ ni yóo máa gbé sunkún tí yóo sì máa payínkeke.
Mat 24:32-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n. Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Noa, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí. Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Noa fi bọ́ sínú ọkọ̀. Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí o ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn. Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a o mú ẹnìkan, a ó sì fi ẹni kejì sílẹ̀. Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹni kejì sílẹ̀. “Nítorí náà, ẹ múra sílẹ̀, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín yóò dé. Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. “Ǹjẹ́ olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́? Alábùkún fún ni ọmọ ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní. Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú náà bá wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘olúwa mi kì yóò tètè dé.’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara. Nígbà náà ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò retí. Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ibùgbé àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.