Mat 24:27-30
Mat 24:27-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de ìwọ-õrun; bẹ̃ni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. Nitori ibikibi ti oku ba gbé wà, ibẹ̀ li awọn igúnnugún ikojọ pọ̀ si. Lojukanna lẹhin ipọnju ọjọ wọnni li õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn, awọn irawọ yio ti oju ọrun já silẹ, agbara oju ọrun li a o si mì titi: Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kãnu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.
Mat 24:27-30 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí bí mànàmáná ti ń kọ ní ìlà oòrùn, tí ó sì ń mọ́lẹ̀ dé ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn gúnnugún yóo péjọ sí. “Lẹsẹkẹsẹ lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ láti ọ̀run. Gbogbo àwọn agbára tí ó wà ní ọ̀run ni a óo mì jìgìjìgì. Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá.
Mat 24:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí. “Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, “ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’ “Nígbà náà ni ààmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.