Mat 24:18-20
Mat 24:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki ẹniti mbẹ li oko maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! Ẹ si mã gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutù, tabi ọjọ isimi
Pín
Kà Mat 24Mat 24:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti lọ mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀. Ó ṣe! Fún àwọn aboyún ati fún àwọn tí wọn bá ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ ní ọjọ́ náà. Ẹ gbadura pé kí sísá yín má bọ́ sí ìgbà òtútù nini, tabi sí Ọjọ́ Ìsinmi.
Pín
Kà Mat 24Mat 24:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn. Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi.
Pín
Kà Mat 24