Mat 24:1-51

Mat 24:1-51 Bibeli Mimọ (YBCV)

JESU si jade lọ, o ti tẹmpili kuro: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá lati fi kikọ́ tẹmpili hàn a. Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ri gbogbo nkan wọnyi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Kì yio si okuta kan nihinyi ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ. Bi o si ti joko lori òke Olifi, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá nikọ̀kọ, wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? Kini yio si ṣe àmi wíwa rẹ, ati ti opin aiye? Jesu si dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ. Nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn ó si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ. Ẹnyin o si gburo ogun ati idagìri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi ko le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: ìyan, ati ajakalẹ-arùn, ati iṣẹlẹ̀ yio si wà ni ibi pipọ. Gbogbo nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju. Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni ìya, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ède nitori orukọ mi. Nigbana li ọ̀pọlọpọ yio kọsẹ̀, nwọn o si ma ṣòfofo ara wọn, nwọn o si mã korira ara wọn. Wolĩ eke pipọ ni yio si dide, nwọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ. Ati nitori ẹ̀ṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù. Ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà. A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de. Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:) Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sálọ si ori òke: Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o maṣe sọkalẹ wá imu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀: Ki ẹniti mbẹ li oko maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! Ẹ si mã gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutù, tabi ọjọ isimi: Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹ̃kọ, irú rẹ̀ kì yio si si. Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là a; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru. Nigbana bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, Wo o, Kristi mbẹ nihin, tabi lọhun; ẹ máṣe gbà a gbọ́. Nitori awọn eke Kristi, ati eke wolĩ yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu nla hàn; tobẹ̃ bi o le ṣe ṣe nwọn o tàn awọn ayanfẹ pãpã. Wo o, mo wi fun nyin tẹlẹ. Nitorina bi nwọn ba wi fun nyin pe, Wo o, o wà li aginjù; ẹ má lọ sibẹ̀: wo o, o wà ni iyẹwu; ẹ máṣe gbàgbọ́. Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de ìwọ-õrun; bẹ̃ni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. Nitori ibikibi ti oku ba gbé wà, ibẹ̀ li awọn igúnnugún ikojọ pọ̀ si. Lojukanna lẹhin ipọnju ọjọ wọnni li õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn, awọn irawọ yio ti oju ọrun já silẹ, agbara oju ọrun li a o si mì titi: Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kãnu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla. Yio si rán awọn angẹli rẹ̀ ti awọn ti ohùn ipè nla, nwọn o si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji. Njẹ ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; nigbati ẹká rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile: Gẹgẹ bẹ̃ li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ. Ọrun on aiye yio rekọjá, ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja. Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ̀ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo. Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio si ri. Nitori bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kikún omi, ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ́ sinu ọkọ̀, Nwọn kò si mọ̀ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. Nigbana li ẹni meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi èkejì silẹ. Awọn obinrin meji yio jùmọ ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin kò mọ̀ wakati ti Oluwa nyin yio de. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati na ti olè yio wá, iba ma ṣọna, on kì ba ti jẹ́ ki a runlẹ ile rẹ̀. Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de. Tani iṣe olõtọ ati ọlọgbọn ọmọ-ọdọ, ẹniti oluwa rẹ̀ fi ṣe olori ile rẹ̀, lati fi onjẹ wọn fun wọn li akokò? Alabukún-fun li ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ẹniti yio bá a ki o mã ṣe bẹ̃. Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, On o fi ṣe olori gbogbo ohun ti o ni. Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ buburu na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi fà àbọ rẹ̀ sẹhin; Ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọ̀muti; Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti, ati ni wakati ti kò daba. Yio si jẹ ẹ ni ìya gidigidi, yio yàn ipa rẹ̀ pẹlu awọn agabagebe, nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

Mat 24:1-51 Yoruba Bible (YCE)

Jesu jáde kúrò ninu Tẹmpili. Bí ó ti ń lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n pe akiyesi rẹ̀ sí bí a ti ṣe kọ́ ilé náà. Ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí gbogbo ilé yìí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní ku òkúta kan lórí ekeji tí wọn kò ní wó palẹ̀.” Nígbà tí Jesu jókòó lórí Òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀, kí sì ni àmì àkókò wíwá rẹ ati ti òpin ayé?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ ni yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo máa sọ pé, ‘Èmi gan-an ni Mesaya náà,’ wọn yóo sì tan ọpọlọpọ jẹ. Àkókò ń bọ̀ tí ẹ óo gbúròó ogun ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun. Ẹ má bẹ̀rù. Èyí níláti rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kò ì tíì tó àkókò tí òpin ayé yóo dé. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo dìde sí orílẹ̀-èdè; ìjọba yóo dìde sí ìjọba. Ìyàn yóo mú. Ilẹ̀ yóo máa mì ní ọpọlọpọ ìlú. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora bíi ti ìrọbí ni gbogbo èyí. “Ní àkókò náà, wọn yóo fà yín lé àwọn eniyan lọ́wọ́ pé kí wọ́n jẹ yín níyà, kí wọ́n sì pa yín. Gbogbo ará ayé ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ọpọlọpọ yóo kùnà ninu igbagbọ; wọn yóo tú àwọn mìíràn fó; wọn yóo sì kórìíra àwọn mìíràn. Ọpọlọpọ àwọn wolii èké ni yóo dìde, wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ. Nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ yóo gbilẹ̀, ìfẹ́ ọpọlọpọ yóo rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forí tì í títí dé òpin, òun ni a óo gbà là. A óo waasu ìyìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé. “Nígbà náà ni ẹ óo rí ohun ẹ̀gbin tí wolii Daniẹli ti sọ tẹ́lẹ̀, tí ó dúró ní ibi mímọ́ (ìwọ olùkàwé yìí, jẹ́ kí ohun tí ò ń kà yé ọ). Tí èyí bá ti ṣẹlẹ̀, kí àwọn tí ó wà ní Judia sálọ sí orí òkè. Ẹni tí ó wà lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kò gbọdọ̀ sọ̀kalẹ̀ wọlé lọ mú àwọn ohun ìní rẹ̀. Ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti lọ mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀. Ó ṣe! Fún àwọn aboyún ati fún àwọn tí wọn bá ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ ní ọjọ́ náà. Ẹ gbadura pé kí sísá yín má bọ́ sí ìgbà òtútù nini, tabi sí Ọjọ́ Ìsinmi. Nítorí ìpọ́njú yóo pọ̀ ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyìí; irú rẹ̀ kò sì tún ní sí mọ́. Bí Ọlọrun kò bá dín àwọn ọjọ́ náà kù ni, ẹ̀dá kankan kì bá tí là. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́, Ọlọrun yóo dín àwọn ọjọ́ náà kù. “Ní àkókò náà, bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, ‘Wò ó! Mesaya náà nìyí níhìn-ín!’ Tabi ‘Wò ó! Mesaya ló wà lọ́hùn-ún nì!’ ẹ má ṣe gbàgbọ́. Nítorí àwọn Mesaya èké ati àwọn wolii èké yóo dìde. Wọn yóo fi àmì ńlá hàn, wọn yóo sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ; bí ó bá ṣeéṣe fún wọn, wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ. Ẹ wò ó, ogun àsọtẹ́lẹ̀ nìyí. “Nítorí náà, bí wọn bá sọ fun yín pé, ‘Ẹ wá wò ó ní aṣálẹ̀,’ ẹ má lọ. Tabi tí wọ́n bá sọ pé, ‘Ẹ wá wò ó ní ìyẹ̀wù,’ ẹ má ṣe gbàgbọ́. Nítorí bí mànàmáná ti ń kọ ní ìlà oòrùn, tí ó sì ń mọ́lẹ̀ dé ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn gúnnugún yóo péjọ sí. “Lẹsẹkẹsẹ lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ láti ọ̀run. Gbogbo àwọn agbára tí ó wà ní ọ̀run ni a óo mì jìgìjìgì. Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá. Yóo wá rán angẹli rẹ̀ pẹlu fèrè ńlá, wọn yóo kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé; àní láti ìkangun ọ̀run kan dé ìkangun keji. “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọnyi, kí ẹ̀yin náà mọ̀ pé àkókò súnmọ́ tòsí, ó ti dé ẹnu ọ̀nà. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán títí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ. “Kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ náà ati wakati náà. Àwọn angẹli ọ̀run kò mọ̀ ọ́n; ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan ni ó mọ̀ ọ́n. Nítorí bí ó ti rí ní ìgbà Noa, bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Nítorí ní àkókò náà, kí ìkún-omi tó dé, ńṣe ni wọ́n ń jẹ, tí wọn ń mu, wọ́n ń gbé iyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí ó fi di ọjọ́ tí Noa wọ inú ọkọ̀. Wọn kò fura títí ìkún-omi fi dé, tí ó gba gbogbo wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Àwọn meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. Àwọn obinrin meji yóo máa lọ ọkà ninu ilé ìlọkà. A óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Oluwa yín ń bọ̀. Ẹ mọ èyí pé bí baálé bá mọ àsìkò tí olè yóo dé, ìbá máa ṣọ́nà, kì bá tí jẹ́ kí olè kó ilé rẹ̀. Nítorí náà, kí ẹ̀yin náà wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wakati tí ẹ kò rò tẹ́lẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo dé. “Bí ẹrú kan bá jẹ́ olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n, ọ̀gá rẹ̀ á fi ilé rẹ̀ lé e lọ́wọ́, pé kí ó máa fún àwọn eniyan ní oúnjẹ lásìkò. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹrú náà tí ọ̀gá rẹ̀ bá bá a lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo fi í ṣe olùtọ́jú ohun gbogbo tí ó ní. Ṣugbọn bí ẹrú bá jẹ́ olubi, tí ó bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi kò ní tètè dé!’ Tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu pẹlu àwọn ọ̀mùtí, ọ̀gá ẹrú náà yóo dé ní ọjọ́ tí kò rò, ati ní wakati tí kò lérò. Ọ̀gá rẹ̀ yóo wá nà án, yóo fi í sí ààrin àwọn alaiṣootọ. Níbẹ̀ ni yóo máa gbé sunkún tí yóo sì máa payínkeke.

Mat 24:1-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí Jesu ti ń kúrò ni tẹmpili, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n fẹ́ fi ẹwà tẹmpili náà hàn án. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín gbogbo ilé yìí ni a yóò wó lulẹ̀, kò ní sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí òmíràn, tí a kì yóò wó lulẹ̀.” Bí ó ti jókòó ní orí òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, “Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ ààmì ìpadà wá rẹ, àti ti òpin ayé?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kristi náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀. “Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi. Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà. A ó sì wàásù ìhìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé. “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e). Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Judea sálọ sí àwọn orí òkè. Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn. Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi. Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí. “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́. Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ. Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀. “Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá, ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́. Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí. “Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, “ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’ “Nígbà náà ni ààmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá. Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ. “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n. Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Noa, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí. Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Noa fi bọ́ sínú ọkọ̀. Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí o ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn. Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a o mú ẹnìkan, a ó sì fi ẹni kejì sílẹ̀. Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹni kejì sílẹ̀. “Nítorí náà, ẹ múra sílẹ̀, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín yóò dé. Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. “Ǹjẹ́ olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́? Alábùkún fún ni ọmọ ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní. Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú náà bá wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘olúwa mi kì yóò tètè dé.’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara. Nígbà náà ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò retí. Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ibùgbé àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.