Mat 24:1-22

Mat 24:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

JESU si jade lọ, o ti tẹmpili kuro: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá lati fi kikọ́ tẹmpili hàn a. Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ri gbogbo nkan wọnyi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Kì yio si okuta kan nihinyi ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ. Bi o si ti joko lori òke Olifi, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá nikọ̀kọ, wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? Kini yio si ṣe àmi wíwa rẹ, ati ti opin aiye? Jesu si dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ. Nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn ó si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ. Ẹnyin o si gburo ogun ati idagìri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi ko le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: ìyan, ati ajakalẹ-arùn, ati iṣẹlẹ̀ yio si wà ni ibi pipọ. Gbogbo nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju. Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni ìya, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ède nitori orukọ mi. Nigbana li ọ̀pọlọpọ yio kọsẹ̀, nwọn o si ma ṣòfofo ara wọn, nwọn o si mã korira ara wọn. Wolĩ eke pipọ ni yio si dide, nwọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ. Ati nitori ẹ̀ṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù. Ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà. A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de. Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:) Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sálọ si ori òke: Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o maṣe sọkalẹ wá imu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀: Ki ẹniti mbẹ li oko maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! Ẹ si mã gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutù, tabi ọjọ isimi: Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹ̃kọ, irú rẹ̀ kì yio si si. Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là a; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru.

Mat 24:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Jesu jáde kúrò ninu Tẹmpili. Bí ó ti ń lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n pe akiyesi rẹ̀ sí bí a ti ṣe kọ́ ilé náà. Ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí gbogbo ilé yìí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní ku òkúta kan lórí ekeji tí wọn kò ní wó palẹ̀.” Nígbà tí Jesu jókòó lórí Òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀, kí sì ni àmì àkókò wíwá rẹ ati ti òpin ayé?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ ni yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo máa sọ pé, ‘Èmi gan-an ni Mesaya náà,’ wọn yóo sì tan ọpọlọpọ jẹ. Àkókò ń bọ̀ tí ẹ óo gbúròó ogun ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun. Ẹ má bẹ̀rù. Èyí níláti rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kò ì tíì tó àkókò tí òpin ayé yóo dé. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo dìde sí orílẹ̀-èdè; ìjọba yóo dìde sí ìjọba. Ìyàn yóo mú. Ilẹ̀ yóo máa mì ní ọpọlọpọ ìlú. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora bíi ti ìrọbí ni gbogbo èyí. “Ní àkókò náà, wọn yóo fà yín lé àwọn eniyan lọ́wọ́ pé kí wọ́n jẹ yín níyà, kí wọ́n sì pa yín. Gbogbo ará ayé ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ọpọlọpọ yóo kùnà ninu igbagbọ; wọn yóo tú àwọn mìíràn fó; wọn yóo sì kórìíra àwọn mìíràn. Ọpọlọpọ àwọn wolii èké ni yóo dìde, wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ. Nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ yóo gbilẹ̀, ìfẹ́ ọpọlọpọ yóo rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forí tì í títí dé òpin, òun ni a óo gbà là. A óo waasu ìyìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé. “Nígbà náà ni ẹ óo rí ohun ẹ̀gbin tí wolii Daniẹli ti sọ tẹ́lẹ̀, tí ó dúró ní ibi mímọ́ (ìwọ olùkàwé yìí, jẹ́ kí ohun tí ò ń kà yé ọ). Tí èyí bá ti ṣẹlẹ̀, kí àwọn tí ó wà ní Judia sálọ sí orí òkè. Ẹni tí ó wà lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kò gbọdọ̀ sọ̀kalẹ̀ wọlé lọ mú àwọn ohun ìní rẹ̀. Ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti lọ mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀. Ó ṣe! Fún àwọn aboyún ati fún àwọn tí wọn bá ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ ní ọjọ́ náà. Ẹ gbadura pé kí sísá yín má bọ́ sí ìgbà òtútù nini, tabi sí Ọjọ́ Ìsinmi. Nítorí ìpọ́njú yóo pọ̀ ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyìí; irú rẹ̀ kò sì tún ní sí mọ́. Bí Ọlọrun kò bá dín àwọn ọjọ́ náà kù ni, ẹ̀dá kankan kì bá tí là. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́, Ọlọrun yóo dín àwọn ọjọ́ náà kù.

Mat 24:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí Jesu ti ń kúrò ni tẹmpili, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n fẹ́ fi ẹwà tẹmpili náà hàn án. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín gbogbo ilé yìí ni a yóò wó lulẹ̀, kò ní sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí òmíràn, tí a kì yóò wó lulẹ̀.” Bí ó ti jókòó ní orí òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, “Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ ààmì ìpadà wá rẹ, àti ti òpin ayé?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kristi náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀. “Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi. Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà. A ó sì wàásù ìhìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé. “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e). Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Judea sálọ sí àwọn orí òkè. Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn. Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi. Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí. “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú.