Mat 23:5-12
Mat 23:5-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn. Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu, Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi. Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin. Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun. Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi. Ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin. Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ li a o gbé ga.
Mat 23:5-12 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí eniyan lè rí wọn ni. Wọn á di tírà pàlàbà-pàlàbà mọ́ iwájú. Wọn á ṣe waja-waja ńláńlá sí etí aṣọ wọn. Wọ́n fẹ́ràn ìjókòó ọlá níbi àsè. Wọ́n fẹ́ràn àga iwájú ní ilé ìpàdé. Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’ Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́. Ẹ má pe ẹnìkan ní ‘Baba’ ní ayé, nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni Baba yín, ẹni tí ó wà ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè yín ní ‘Ọ̀gá,’ nítorí ọ̀gá kanṣoṣo ni ẹ ní, òun ni Mesaya. Ẹni tí ó bá lọ́lá jùlọ láàrin yín ni kí ó ṣe iranṣẹ yín. Ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.
Mat 23:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni: Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’ “Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín. Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run. Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbéga.