Mat 23:23-39
Mat 23:23-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi agabagebe; nitoriti ẹnyin ngbà idamẹwa minti, ati anise, ati kumini, ẹnyin si ti fi ọ̀ran ti o tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ãnu, ati igbagbọ́: wọnyi li o tọ́ ti ẹnyin iba ṣe, laisi fi iyoku silẹ laiṣe. Ẹnyin afọju amọ̀na, ti nsẹ́ kantikanti ti o si ngbé ibakasiẹ mì. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nfọ̀ ode ago ati awopọkọ́ mọ́, ṣugbọn inu wọn kún fun irẹjẹ ati wọ̀bia. Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ̀ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ́ mọ́ na, ki ode wọn ki o le mọ́ pẹlu. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin dabi ibojì funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo. Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu farahàn li ode bi olododo fun enia, ṣugbọn ninu ẹ kún fun agabagebe ati ẹ̀ṣẹ. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin kọ́ ibojì awọn wolĩ, ẹnyin si ṣe isà okú awọn olododo li ọṣọ, Ẹnyin si wipe, Awa iba wà li ọjọ awọn baba wa, awa kì ba li ọwọ́ ninu ẹ̀jẹ awọn wolĩ. Njẹ ẹnyin li ẹlẹri fun ara nyin pe, ẹnyin li awọn ọmọ awọn ẹniti o pa awọn wolĩ. Njẹ ẹnyin kuku kún òṣuwọn baba nyin de oke. Ẹnyin ejò, ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin o ti ṣe yọ ninu ẹbi ọrun apadi? Nitorina ẹ kiyesi i, Emi rán awọn wolĩ, ati amoye, ati akọwe si nyin: omiran ninu wọn li ẹnyin ó pa, ti ẹnyin ó si kàn mọ agbelebu; ati omiran ninu wọn li ẹnyin o nà ni sinagogu nyin, ti ẹnyin o si ṣe inunibini si lati ilu de ilu: Ki gbogbo ẹ̀jẹ awọn olõtọ, ti a ti ta silẹ li aiye, ba le wá sori nyin, lati ẹ̀jẹ Abeli olododo titi de ẹ̀jẹ Sakariah ọmọ Barakiah, ẹniti ẹnyin pa larin tẹmpili ati pẹpẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo nkan wọnyi ni yio wá sori iran yi. Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn wolĩ, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! Sawò o, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro. Mo si wi fun nyin, Ẹnyin kì yio ri mi mọ́ lati isisiyi lọ, titi ẹnyin o fi wipe, Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.
Mat 23:23-39 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi! Ẹ̀ ń san ìdámẹ́wàá àwọn èròjà ọbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ eléwé, nígbà tí ẹ gbàgbé àwọn ohun tí ó ṣe pataki ninu òfin: bíi ìdájọ́ òdodo, àánú, ati igbagbọ. Àwọn ohun tí ẹ̀ bá mójútó nìyí, láì gbàgbé ìdámẹ́wàá. Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan! Ẹ̀ ń yọ kòkòrò tín-tìn-tín kúrò ninu ohun tí ẹ̀ ń mu, ṣugbọn ẹ̀ ń gbé ràkúnmí mì mọ́ omi yín! “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn. Ẹ̀ ń fọ òde ife ati òde àwo oúnjẹ nígbà tí inú wọn kún fún àwọn ohun tí ẹ fi ìwà olè ati ìwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan já gbà. Ìwọ afọ́jú Farisi! Kọ́kọ́ fọ inú ife ná, òde rẹ̀ náà yóo sì mọ́. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ dàbí àwọn ibojì tí a kùn ní funfun, tí ó dùn-ún wò lóde, ṣugbọn inú wọn kún fún egungun òkú ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ̀yin náà rí lóde, lójú àwọn eniyan ẹ dàbí ẹni rere, ṣugbọn ẹ kún fún àṣehàn ati ìwà burúkú. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ̀ ń ṣe ibojì fún àwọn wolii, ẹ sì ń ṣe ibojì àwọn eniyan rere lọ́ṣọ̀ọ́. Ẹ wá ń sọ pé, ‘Bí ó bá jẹ́ pé a wà ní ìgbà àwọn baba wa, àwa kò bá tí lọ́wọ́ ninu ikú àwọn wolii.’ Nípa gbolohun yìí, ẹ̀ ń jẹ́rìí sí ara yín pé ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wolii ni yín. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin náà ẹ múra, kí ẹ parí ohun tí àwọn baba yín ṣe kù! Ẹ̀yin ejò, ìran paramọ́lẹ̀! Báwo ni ẹ kò ti ṣe ní gba ìdájọ́ ọ̀run àpáàdì? Nítorí èyí ni mo fi rán àwọn wolii, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ati àwọn amòfin si yín. Ẹ óo pa òmíràn ninu wọn, ẹ óo sì kan òmíràn mọ́ agbelebu. Ẹ óo na àwọn mìíràn ninu wọn ní ilé ìpàdé yín, ẹ óo sì máa lépa wọn láti ìlú dé ìlú. Ẹ óo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi kí ẹ lè fi orí gba ẹ̀bi ikú gbogbo eniyan rere tí ẹ ti ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀; ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí Abeli, ẹni rere títí fi dé orí Sakaraya, ọmọ Berekaya, tí ẹ pa láàrin àgọ́ mímọ́ ati pẹpẹ ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo fi orí fá gbogbo ẹ̀bi yìí. “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ àwọn tí a rán sí ọ ní òkúta pa! Ìgbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tí ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́! Ṣugbọn o kọ̀ fún mi. Wò ó, a óo sọ Tẹmpili rẹ di ahoro. Nítorí náà, mo sọ fun yín pé ẹ kò ní fojú kàn mí mọ́ títí di àkókò tí ẹ óo wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa!’ ”
Mat 23:23-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe. Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fi afọ́jú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò-kantíkantí tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ìbákasẹ mì. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo. Ìwọ afọ́jú Farisi, tètè kọ́ fọ inú ago àti àwo, gbogbo ago náà yóò sì di mímọ́. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì funfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́. Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè, nítorí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì tí í ṣe ibojì àwọn olódodo ní ọ̀ṣọ́. Ẹ̀yin sì wí pé, Àwa ìbá wà ní àsìkò àwọn baba wa, àwa kì bá ní ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì. Ǹjẹ́ ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí fún ara yín pé, ẹ̀yin ni ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wòlíì. Àti pé, ẹ̀yin ń tẹ̀lé ìṣísẹ̀ àwọn baba yín. Ẹ̀yin ń kún òṣùwọ̀n ìwà búburú wọn dé òkè. “Ẹ̀yin ejò! Ẹ̀yin paramọ́lẹ̀! Ẹ̀yin yóò ti ṣe yọ nínú ẹ̀bi ọ̀run àpáàdì? Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú Sinagọgu yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú. Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wà sórí ìran yìí. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀. Wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Nítorí èmi sọ èyí fún yín, ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́, títí ẹ̀yin yóò fi sọ pé ‘Olùbùkún ni ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa.’ ”