Mat 23:1-4
Mat 23:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jesu wi fun ijọ enia, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Pe, Awọn akọwe pẹlu awọn Farisi joko ni ipò Mose: Nitorina ohunkohun gbogbo ti nwọn ba wipe ki ẹ kiyesi, ẹ mã kiyesi wọn ki ẹ si mã ṣe wọn; ṣugbọn ẹ má ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: nitoriti nwọn a ma wi, ṣugbọn nwọn ki iṣe. Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na.
Mat 23:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Jesu bá sọ fún àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ni olùtúmọ̀ òfin Mose. Nítorí náà, ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fun yín ni kí ẹ ṣe. Ṣugbọn ẹ má ṣe tẹ̀lé ìwà wọn, nítorí ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo sọ, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo ṣe. Wọn á di ẹrù wúwo, wọn á gbé e ka àwọn eniyan lórí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn fúnra wọn kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn kan ẹrù náà.
Mat 23:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose, Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an.