Mat 23:1-10
Mat 23:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jesu wi fun ijọ enia, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Pe, Awọn akọwe pẹlu awọn Farisi joko ni ipò Mose: Nitorina ohunkohun gbogbo ti nwọn ba wipe ki ẹ kiyesi, ẹ mã kiyesi wọn ki ẹ si mã ṣe wọn; ṣugbọn ẹ má ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: nitoriti nwọn a ma wi, ṣugbọn nwọn ki iṣe. Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na. Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn. Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu, Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi. Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin. Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun. Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi.
Mat 23:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Jesu bá sọ fún àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ni olùtúmọ̀ òfin Mose. Nítorí náà, ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fun yín ni kí ẹ ṣe. Ṣugbọn ẹ má ṣe tẹ̀lé ìwà wọn, nítorí ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo sọ, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo ṣe. Wọn á di ẹrù wúwo, wọn á gbé e ka àwọn eniyan lórí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn fúnra wọn kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn kan ẹrù náà. Gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí eniyan lè rí wọn ni. Wọn á di tírà pàlàbà-pàlàbà mọ́ iwájú. Wọn á ṣe waja-waja ńláńlá sí etí aṣọ wọn. Wọ́n fẹ́ràn ìjókòó ọlá níbi àsè. Wọ́n fẹ́ràn àga iwájú ní ilé ìpàdé. Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’ Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́. Ẹ má pe ẹnìkan ní ‘Baba’ ní ayé, nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni Baba yín, ẹni tí ó wà ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè yín ní ‘Ọ̀gá,’ nítorí ọ̀gá kanṣoṣo ni ẹ ní, òun ni Mesaya.
Mat 23:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose, Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an. “Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni: Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’ “Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín. Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run. Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi.