Mat 22:41-45
Mat 22:41-45 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi awọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu bi wọn, Wipe, Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ tani iṣe? Nwọn wi fun u pe, Ọmọ Dafidi ni. O wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti Dafidi nipa ẹmí fi npè e li Oluwa, wipe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? Njẹ bi Dafidi ba npè e li Oluwa, ẽha ti ri ti o fi ṣe ọmọ rẹ̀?
Mat 22:41-45 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí àwọn Farisi péjọ pọ̀, Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ rò nípa Mesaya, ọmọ ta ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọmọ Dafidi ni.” Ó bá tún bi wọ́n pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí Dafidi tí Dafidi fi pe Mesaya ní ‘Oluwa’? Dafidi sọ pé, ‘OLUWA sọ fún Oluwa mi pé: Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di ohun ìtìsẹ̀ rẹ.’ Bí Dafidi bá pè é ní ‘OLUWA’, báwo ni Mesaya ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
Mat 22:41-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí àwọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ẹ rò nípa Kristi? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?” Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dafidi.” Ó sì wí fún wọn pé, “Kí lo dé tí Dafidi, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé, “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’ Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”