Mat 22:29-32
Mat 22:29-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun. Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun. Ṣugbọn niti ajinde okú, ẹnyin kò ti kà eyi ti a sọ fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye.
Mat 22:29-32 Yoruba Bible (YCE)
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun. Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí. Nípa ti ajinde àwọn òkú, ẹ kò ì tíì ka ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ fun yín pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, Ọlọrun àwọn alààyè ni.”
Mat 22:29-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run. Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn angẹli ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”