Mat 22:23-30
Mat 22:23-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ kanna li awọn Sadusi tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si, nwọn si bi i, Wipe, Olukọni, Mose wipe, Bi ẹnikan ba kú li ailọmọ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe irú dide fun arakunrin rẹ̀. Awọn arakunrin meje kan ti wà lọdọ wa: eyi ekini lẹhin igbati o gbé aya rẹ̀ ni iyawo, o kú, bi kò ti ni irúọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀: Gẹgẹ bẹ̃li ekeji pẹlu, ati ẹkẹta titi o fi de ekeje. Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu. Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun. Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun.
Mat 22:23-30 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ náà, àwọn Sadusi kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n sọ pé kò sí ajinde.) Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, Mose sọ pé bí ẹnìkan bá kú láì ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ fẹ́ aya rẹ̀ kí ó lè bí ọmọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà lọ́dọ̀ wa. Ekinni gbé iyawo, láìpẹ́ ó kú. Nígbà tí kò bí ọmọ, ó fi iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀. Ekeji náà kú, ati ẹkẹta, títí tí àwọn mejeeje fi kú. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obinrin náà wá kú. Tí ó bá di àkókò ajinde, ninu àwọn mejeeje, iyawo ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun. Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí.
Mat 22:23-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusi tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jesu wá láti bi í ní ìbéèrè, Wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mose wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrín wa níhìn-ín yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú ní àìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ. A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e. Bẹ́ẹ̀ sì ni títí tí òun fi di ìyàwó ẹni keje. Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú. Nítorí tí ó ti ṣe ìyàwó àwọn arákùnrin méjèèje, ìyàwó ta ni yóò jẹ́ ní àjíǹde òkú?” Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run. Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn angẹli ní ọ̀run.